Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 22:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́ n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jérúsálẹ́mù àti fún ilée Júdà.

22. Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilée Dáfídì lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá sí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ẹnikẹ́ni kì yóò le è sí.

23. Èmi yóò sì kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní àyèe rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.

24. Gbogbo ògo ìdílée rẹ̀ ni yóò rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ gbogbo ohun èlò aláìlágbára láti orí abọ́ rẹ̀ dé orí ìdẹ̀ rẹ̀.

25. “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní àyèe rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lóríi rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 22