Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 22:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Kíyèṣára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígíríkí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára.

18. Òun yóò ká ọ rúgúdú bí i bọ́ọ̀lùyóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀ èdè ńlá kan.Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú síàti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—ìwọ ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!

19. Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

20. “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliákímù ọmọ Hílíkíyà.

21. Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́ n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jérúsálẹ́mù àti fún ilée Júdà.

22. Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilée Dáfídì lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá sí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ẹnikẹ́ni kì yóò le è sí.

23. Èmi yóò sì kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní àyèe rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 22