Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 2:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí baa ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,

18. gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.

19. Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpátaàti sínú ihò ilẹ̀kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwaàti ògo ọlá ńlá rẹ̀,nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò má a sọàwọn ère fàdákà àti ère wúràtí wọ́n ti yá fún bíbọsí èkúté àti àwọn àdán,

21. Wọn yóò ṣálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpátaàti sínú ihò pàlàpálá àpátakúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwaàti ògo ọlá ńlá rẹ̀,nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22. Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́èmí ẹni tó wà ní imú un rẹ̀kín ni ó jámọ́?

Ka pipe ipin Àìsáyà 2