Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 2:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. nítorí gbogbo igi kedari Lẹ́bánónì, tó ga tó rìpóàti gbogbo óákù Báṣánì,

14. nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńláàti àwọn òkè kéé kèè kéé,

15. fún ilé ìṣọ́ gíga gígaàti àwọn odi ìdáàbòbò,

16. fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwòàwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

17. Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí baa ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,

18. gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.

19. Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpátaàti sínú ihò ilẹ̀kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwaàti ògo ọlá ńlá rẹ̀,nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò má a sọàwọn ère fàdákà àti ère wúràtí wọ́n ti yá fún bíbọsí èkúté àti àwọn àdán,

Ka pipe ipin Àìsáyà 2