Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 19:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Éjíbítì:Kíyèsíi, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́sinó sì ń bọ̀ wá sí Éjíbítì.Àwọn ère òrìṣà Éjíbítì wárìrì níwájúu rẹ̀,ọkàn àwọn ará Éjíbítì sì ti domi nínú un wọn.

2. “Èmi yóò rú àwọn ará Éjíbítì sókè sí ara wọnarákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,aládúgbò yóò dìde sí aládúgbò rẹ̀,ìlú yóò dìde sí ìlú,ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.

3. Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù,èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀.

4. Èmi yóò fi Éjíbítì lé agbáraàwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,ọba aláìláàánú ni yóò jọba lé wọn lórí,”ni Olúwa, Olúwa Alágbára wí.

5. Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,gbogbo ilẹ̀ odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.

6. Àyasí omi yóò máa rùn;àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkùwọn yóò sì gbẹ.Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7. àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú,tí ó wà ní oríṣun odò Náì.Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náìyóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànùtí kò sì ní sí mọ́.

8. Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò,gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí;yóò sì máa rùn.

9. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminúàwọn ahunsọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìṣàn ọkàn yóò ṣe.

11. Àwọn oníṣẹ́ Ṣóánì ti di aláìgbọ́n,àwọn ọlọgbọ́n olùdámọ̀ràn Fáráòń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.Báwo ló ṣe lè sọ fún Fáráò pé,“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba ijọ́un.”

12. Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?Jẹ́ kí wọn fi hàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mímọ̀ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogunti pinnu lórí Éjíbítì.

13. Àwọn oníṣẹ́ Ṣóárì ti di aláìgbọ́n,a ti tan àwọn adarí Méḿfísì jẹ;àwọn òkúta igunlé tí í ṣe ti ènìyàn rẹti ṣi Éjíbítì lọ́nà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 19