Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 17:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dámásíkù:“Kíyèsíí, Dámásíkù kò ní jẹ́ ìlú mọ́ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

2. Àwọn ìlú Áróérì ni a ó kọ̀ sílẹ̀fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn ṣíbẹ̀,láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

3. Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Éfáímù,àti agbára ọba kúrò ní Dámásíkù;àwọn àsẹ́ku Árámù yóò dágẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Ísírẹ́lì,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

4. “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jákọ́bù yóò ṣá;ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

5. Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkóórè kó àwọnirúgbìn tí ó dúró jọtí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Réfémù.

6. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì,tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kùsórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 17