Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 16:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùnránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,Láti Ṣẹ́là, kọjá ní ihà,lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Ṣíhónì.

2. Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ẹ̀rẹ̀ǹbalẹ̀tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Móábùní àwọn ọmọdo Ánónì.

3. “Fún wa ní ìmọ̀rànṣe ìpinnu fún wa.Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru—ní ọ̀sán gangan.Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,má ṣe tú àwọn aṣàtìpó fó

4. Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ,jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”Aninilára yóò wá sí òpin,ìparun yóò dáwọ́;òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 16