Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 15:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Gbogbo omi Nímírímù ni ó ti gbẹàwọn koríko sì ti gbẹ,gbogbo ewéko ti tánewé tútù kankan kò sí mọ́.

7. Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti nítí wọ́n sì tòjọwọ́n ti kó wọn kọjá lọ lóríi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́odò pópúlárì.

8. Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn déìpẹ̀kun ilẹ̀ Móábù;ìpohùnréré wọn lọ títí dé Ẹgíláémù,igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Élímù.

9. Omi Dímónì kún fún ẹ̀jẹ̀,ṣíbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dímónì—kìnnìún kan wá ṣórí àwọn ìṣáǹṣá Móábùàti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 15