Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 14:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Gbogbo wọn yóò dáhùn,wọn yóò wí fún ọ wí pé,“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lúìwọ náà ti dàbí wa.”

11. Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,pẹ̀lú ariwo àwọn hápù rẹ,àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹàwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá,ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayéÌwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí!

13. Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọní ṣónṣó orí òkè mímọ́.

14. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

17. Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”

18. Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 14