Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 13:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn.Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéragaèmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.

12. Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọnju ojúlówóo wúrà lọ,yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà ófírì lọ.

13. Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná an rẹ.

14. Gẹ́gẹ́ bí èkùlù tí à ń dọdẹ rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.

15. Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.

16. Àwọn mọ̀jèsín wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kóàwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.

17. Kíyèsí i, èmi yóò ru àwọn Mẹ́dísì sókè sí wọn,àwọn tí kò bìkítà fún fàdákàtí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.

18. Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;wọn kò ní ṣàánú àwọn mọ̀jèsíntàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.

19. Bábílónì, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọbaògo ìgbéraga àwọn ará Bábílónìni Ọlọ́run yóò dojúrẹ̀ bolẹ̀gẹ́gẹ́ bí Sódómù àti Gòmórà.

20. A kì yóò sì gbé ibẹ̀ mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;Árábù kan yóò fi àgọ́ rẹ lélẹ̀ níbẹ̀,Olùsọ́ àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n àwọn ohun abẹ̀mí aṣálẹ̀ ni yóò gbé bẹ̀,àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,níbẹ̀ ni àwọn òwììwí yóò máa gbéníbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́-igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.

Ka pipe ipin Àìsáyà 13