Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Bábílónìèyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí:

2. Gbé àṣíá ṣókè ní orí òkè gbẹrẹfu,kígbe sí wọn,pè wọ́nláti wọlé sí ẹnu ọ̀nà àwọn Bọ̀rọ̀kìnní.

3. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,mo ti pe àwọn jagunjagun miláti gbé ìbínú mi jádeàwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.

4. Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyànGbọ́, ìdàrúdàpọ̀ láàrin àwọn ìjọba,gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀ èdè! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọàwọn jagunjagun fún ogun.

5. Wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn réré,láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú un rẹ̀—láti pa gbogbo orílẹ̀ èdè náà run.

6. Pohùnréré, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́tòsí,yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.

7. Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.

8. Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,ìrora àti ìpayínkeke yóò dì wọ́n mú,wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.Ẹnìkín-ín-ní yóò wo ẹnìkejìi rẹ̀ pẹ̀lú ìpayàojú wọn á sìgbinájẹ.

9. Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínúàti ìrunú gbígbóná—láti sọ ilẹ̀ náà dahoroàti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú un rẹ̀ run.

Ka pipe ipin Àìsáyà 13