Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 10:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo

2. láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọnàti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúròníwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní lólè.

3. Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirònígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jínjìn wá?Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?

4. Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

5. “Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi,ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

6. Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́runMo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínúláti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógunláti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

7. Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;èrò rẹ̀ ni láti parun,láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.

8. ‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

9. ‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì?Hámátì kò ha dàbí i Ápádì,àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?

Ka pipe ipin Àìsáyà 10