Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 1:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,akẹgbẹ́ àwọn olè,gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn.

24. Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogunAlágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé:“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá min ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.

25. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

26. Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

27. A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà,àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo.

28. Ṣùgbọn àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó pa runÀwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.

29. “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́èyí tí ẹ ní inú dídùn sía ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìítí ẹ ti yàn fúnra yín.

30. Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ tí,tàbí bí ọgbà tí kò ní omi.

31. Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí lẹ́ùiṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,láì sí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 1