Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 9:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Dáfídì sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jónátanì baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”

8. Òun sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”

9. Ọba sì pe Síbà ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Ṣọ́ọ̀lù, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ.

10. Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ró ilé náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkóre wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí òunjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Méfibóṣétì ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣíbà sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)

11. Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Méfibóṣétì, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”

12. Méfibóṣétì sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Síbà ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Méfibóṣétì.

13. Méfibóṣétì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ́ ọba; òun sì yarọ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 9