Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 5:3-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì.

4. Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba; ó sì jọba ní ogójì ọdún.

5. Ó jọba ní Hébírónì ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Júdà: ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.

6. Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn ará Jébúsì, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dáfídì pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ́ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dáfídì kì yóò lè wá síhìn ín.”

7. Ṣùgbọ́n Dáfídì fi agbára gba ìlú odì Síónì: èyí náà ni í ṣe ìlú Dáfídì.

8. Dáfídì sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jébúsì, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dáfídì kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

9. Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì. Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀.

10. Dáfídì sì ń pọ̀ si i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

11. Hírámù ọba Tírè sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, àti igi kédárì, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dáfídì.

12. Dáfídì sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jọba lórí Ísírẹ́lì, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.

13. Dáfídì sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jérúsálẹ́mù wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hébírónì bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dáfídì.

14. Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jérúsálẹ́mù; Ṣamímúà àti Sóbábù, àti Nátanì, àti Sólómónì.

15. Àti Íbéhárì, àti Élíṣúà, àti Néfégì, àti Jáfíà.

16. Àti Élíṣámà, àti Élíádà, àti Élífélétì.

17. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì; Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 5