Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 5:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Àwọn Fílístínì sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Rafaímù.

23. Dáfídì sì bèèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Bákà.

24. Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹṣẹ̀ lórí àwọn igi Bákà náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Fílístínì.”

25. Dáfídì sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un; ó sì kọlu àwọn Fílístínì láti Gébà títí dé Gásérì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 5