1. Gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí pé, “Wò ó, egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa ń ṣe.
2. Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù fi jọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Ísírẹ́lì jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ ó ṣe olùsọ́ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi, ìwọ ó sì jẹ́ olórí fún Ísírẹ́lì.’ ”
3. Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì.
4. Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba; ó sì jọba ní ogójì ọdún.
5. Ó jọba ní Hébírónì ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Júdà: ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.