Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ pé, Ábínérì kú ní Hébírónì, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Ísírẹ́lì sì rẹ̀wẹ̀sì.

2. Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (nítorí pé a sì ka Béérótì pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì).

3. Àwọn ará Béérótì sì ti sá lọ sí Gítaímù, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

4. (Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìhìn dé ní ti Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì láti Jésírẹẹlì wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sá lọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sá lọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Méfíbóṣétì.)

5. Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.

6. Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).

7. Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 4