Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 3:35-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀!”

36. Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsí i, ó sì dára lójú wọn: gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.

37. Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Ábínérì ọmọ Nérì.

38. Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni-ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Ísírẹ́lì.

39. Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Saerúíà sì le jù mí lọ: Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 3