Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 3:25-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ìwọ mọ Ábínérì ọmọ Nérì, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”

26. Nígbà tí Jóábù sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Ábínérì, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sírà: Dáfídì kò sì mọ̀.

27. Ábínérì sì padà sí Hébírónì, Jóabù sì bá a tẹ̀ láàrin ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhẹ́lì arákùnrin rẹ̀.

28. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Ábínérì ọmọ Nérì:

29. Jẹ́ kí ó wà ní orí Jóabù, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní àrùn ìṣun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi ìdà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Jóábù.”

30. (Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì pa Ábínérì, nítorí pé òun ti pa Áṣáhélì arákùnrin wọn ní Gíbíónì ní ogun.)

31. Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.

32. Wọ́n sì sin Ábínérì ní Hébírónì: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkùn ní ibojì Ábínérì; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sunkún.

33. Ọba sì sọkún lórí Ábínérì, ó sì wí pé,“Ǹjẹ́ Ábínérì; yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?

34. A kò sáà dè ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà.Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.”Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.

35. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀!”

36. Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsí i, ó sì dára lójú wọn: gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.

37. Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Ábínérì ọmọ Nérì.

38. Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni-ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 3