Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 24:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì, ó sì ti Dáfídì sí wọn, pé, “Lọ ka iye Ísírẹ́lì àti Júdà!”

2. Ọba sì wí fún Jóábù Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsìnyìí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíásébà, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”

3. Jóábù sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún ìye àwọn ènìyàn náà, ìyekíye kí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọrọrún, ojú Olúwa mi ọba yóò sì rí i: ṣùgbọ́n èétiṣe tí Olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 24