Ọba sì wí fún Jóábù Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsìnyìí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíásébà, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”