Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:39-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.

40. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.

41. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi,èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run.

42. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.

43. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22