Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:38-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.

39. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.

40. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.

41. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi,èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run.

42. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.

43. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

44. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.

45. Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi;bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi.

46. Àyà yóò pá àwọn àlejò,wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.

47. “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.

48. Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22