Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 22:30-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárin ogun kọjá;nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.

31. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò.Òun sì niaṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

32. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.

33. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.

34. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.

35. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.

36. Ìwọ sì ti fún mi ní àsàìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.

37. Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi;tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.

38. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.

39. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.

40. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.

41. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi,èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run.

42. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.

43. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

44. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 22