Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 21:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà.

13. Ó sì mú egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.

14. Wọ́n sì sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jònátánì ọmọ rẹ̀ ní ilé Bẹ́ńjámínì, ní Sélà, nínú ibojì Kíṣì baba rẹ̀: wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ: lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.

15. Ogun sì tún wà láàrin àwọn Fílístínì àti Ísírẹ́lì; Dáfídì sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Fílístínì jà: ó sì rẹ Dáfídì.

16. Iṣibi-bénóbù sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òmìrán, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀dúnrún ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dáfídì.

17. Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Fílístínì náà, ó sì paá, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí iwọ má ṣe pa iná Ísírẹ́lì.”

18. Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì ní Góbù: nígbà náà ni Síbékáì ará Húṣà pa Sáfù, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn òmìrán.

19. Ìjà kan sì tún wà ní Góbù láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa arákùnrin Gòláyátì, ará Gátì, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdúbú igi tí a fi ń hun aṣọ.

20. Ìjà kan sì tún wà ní Gátì, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹṣẹ̀ mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní òmìrán.

21. Nígbà tí òun sì pe Ísírẹ́lì ní ìjà. Jónátanì ọmọ Ṣíméhì arákùnrin Dáfídì sì pa á.

22. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni a bí ní òmìrán ní Gátì, wọ́n sì ti ọwọ́ Dáfídì ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 21