Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 20:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti tòótọ́ ní Ísírẹ́lì: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Ísírẹ́lì: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”

20. Jóábù sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun.

21. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Éfúráímù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà, ọmọ Bíkírì, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sòkè sí ọba, àní sí Dáfídì: fi òun nìkanṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”Obìnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odì wá.”

22. Obìnrin náà sì mú ìmọ́ran rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣébà ọmọ Bíkírì lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Jóábù. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká sọ́dọ̀ ọba.

23. Jóábù sì ni olórí gbogbo ogun Ísírẹ́lì: Bénáyà ọmọ Jéhóiádà sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì, àti ti àwọn Pélétì.

24. Ádórámù sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde: Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.

25. Ṣéfà sì jẹ́ akọ̀wé: Sádókù àti Ábíátarì sì ni àwọn àlùfáà.

26. Írà pẹ̀lú, ará Jáírì ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dáfídì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 20