Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 2:5-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ó rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jábésì Gílíádì láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Ṣọ́ọ̀lù ọ̀gá yín nípa sí sin ín.

6. Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí.

7. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Ṣọ́ọ̀lù ọba yín ti kú, ilé Júdà sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”

8. Lákòókò yìí, Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ṣọ́ọ̀lù ti mú Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì mú un kọjá sí Máhánáímù.

9. Ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì Áṣúrì àti Jésérẹ́lì àti lórí Éfúráímù àti lórí Bẹ́ńjámínì àti lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

10. Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba fún ọdún méjì. Ilé Júdà sì ń tọ Dáfídì lẹ́yìn.

11. Gbogbo àkókò tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

12. Ábínérì ọmọ Nérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Íṣíbóṣetì ọmọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù, wọ́n sì lọ sí Gíbíónì.

13. Jóábù ọmọ Sérúíà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dáfídì jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gíbíónì. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.

14. Nígbà náà, Ábínérì sọ fún Jóábù pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”Jóábù sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é,”

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Bẹ́ńjámínì àti Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù àti méjìlá fún Dáfídì.

16. Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gíbíónì ti à ń pè ni Helikatihu Hasurímù.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 2