Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 2:24-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Jóábù àti Ábíṣáì sì lépa Ábínérì: òòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Ámímà tí o wà níwájú Gíà lọ́nà ijù Gíbíónì.

25. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Ábínérì, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan.

26. Ábínérì sì pe Jóábù, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parún títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kòì tí ì mọ̀ pé yóò korò nikẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.”

27. Jóábù sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.”

28. Jóábù sì fọ́n ipè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Ísírẹ́lì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́.

29. Ábínérì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bítírónì, wọ́n sì wá sí Mahanáímù.

30. Jóábù sì dẹ́kún àti máa tọ Ábínérì lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kándínlógún ni ó kú pẹ̀lú Áṣáhélì nínú àwọn ìránṣẹ Dáfídì.

31. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ Dáfídì sì pá nínú àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì: nínú àwọn ọmọkùnrin Ábínérì; òjìdínní-rinwó ènìyàn.

32. Wọ́n si gbé Ásáhélì wọ́n sì sinín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Jóábù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hébírónì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 2