Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 2:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ábínérì ọmọ Nérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Íṣíbóṣetì ọmọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù, wọ́n sì lọ sí Gíbíónì.

13. Jóábù ọmọ Sérúíà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dáfídì jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gíbíónì. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.

14. Nígbà náà, Ábínérì sọ fún Jóábù pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”Jóábù sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é,”

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Bẹ́ńjámínì àti Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù àti méjìlá fún Dáfídì.

16. Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gíbíónì ti à ń pè ni Helikatihu Hasurímù.

17. Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì ṣẹ́gun Ábínérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì.

18. Àwọn ọmọkùnrin Serúíà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Jóábù, Ábíṣáì àti Ásáhélì. Nísinsìnyìí ẹṣẹ̀ Ásáhélì sì fẹ́rẹ̀ bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín tí ó wà ní pápá.

19. Ó ń lé Ábínérì, kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì bí ó ti ń lé e.

20. Ábínérì bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Ásáhélì ni?”Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”

21. Nígbà náà, Ábínérì sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Ásáhélì kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀.

22. Ábínérì tún kìlọ̀ fún Ásáhélì, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Jóábù lójú?”

23. Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Ábínérì sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ́, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Ásáhélì gbé ṣúbú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 2