Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 19:27-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún Olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ni Olúwa mi ọba rí: nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ.

28. Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sáà rí níwájú Olúwa mi ọba: ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrin àwọn tí ó ń jẹ́un ní ibi oúnjẹ́. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.”

29. Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sáà ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣíbà pín ilẹ̀ náà.”

30. Méfíbóṣétì sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí Olúwa mi ọba sáà ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà.”

31. Básíláì ará Gílíádì sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelímù wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jódánì, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jódánì.

32. Básíláì sì jẹ́ arúgbó ọkùnrìn gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni: ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Máhánáímù; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe.

33. Ọba sì wí fún Básíláì pé, “Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pésè fún ọ ní Jérúsálẹ́mù.”

34. Básíláì sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù

35. Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún Olúwa mi ọba.

36. Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jódánì; èésì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi.

37. Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá Olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”

38. Ọba sì dáhùn wí pé, “Kímhámù yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣeé fún ọ.”

39. Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jódánì ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.

40. Ọba sì ń lọ́ sí Gílígálì, Kímhámù sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbò àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

41. Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jódánì, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dáfídì pẹ̀lú rẹ?”

42. Gbogbo ọkùnrin Júdà sì dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú òúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”

43. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì náà sì dá àwọn ọkùnrin Júdà lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dáfídì jù yín lọ, èésì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?”Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Júdà sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 19