Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 19:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. A sì rò fún Jóábù pe, “Wò ó, ọba ń sunkun, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Ábúsálómù.”

2. Ìṣẹ́gun ijọ́ náà sì di ààwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ijọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀.

3. Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ijọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà.

4. Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Áì! Ọmọ mi Ábúsálómù! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”

5. Jóábù sì wọ inú ile tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ.

6. Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kóríra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbáṣe pé Ábúsálómù wà láàyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.

7. Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsinyìí.”

8. Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba: nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 19