Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 18:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ẹgbàáwá ènìyàn.

8. Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà: igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà.

9. Ábúsálómù sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ábúsálómù sì gun orí ìbaka kan, ìbaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.

10. Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi rí Ábúsálómù so rọ̀ láàrin igi óákù kan.”

11. Jóábù sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.”

12. Ọkùnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Ábíṣáì, àti Ítaì, pé, ‘Ẹ kíyèsí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù.’

13. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi: nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkárarẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.”

14. Jóábù sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Ábúsálómù ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láàyè ní agbede-méjì igi óákù náà.

15. Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Jóábù sì yí Ábúsálómù ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á,

16. Jóábù sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Ísírẹ́lì: nítorí Jóábù ti pe àwọn ènìyàn náà padà.

17. Wọ́n sì gbé Ábúsálómù, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Ísírẹ́lì sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀.

18. Ábúsálómù ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ̀n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì ọba: nítorí tí ó wí pé, Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí: òun sì pe ọ̀wọ̀n náà nípa orúkọ rẹ̀: a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Ábúsálómù.

19. Áhímásì ọmọ Sádókù sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìhìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀ta rẹ̀.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 18