Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 18:30-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró nìhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́.

31. Sì wò ó, Kúṣì sì wí pé, “Ìhìnrere fún Olúwa mi ọba: nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.”

32. Ọba sì bi Kúṣì pé, “Àlàáfíà kọ́ Ábúsálómù ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?”Kúṣì sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀ta Olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.”

33. Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sunkún; bayìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Ábúsálómù! Ọmọ mi! Ọmọ mí Ábúsálómù! Áì! Ìbáṣepé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 18