Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 18:22-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Áhímásì ọmọ Sádókù sì tún wí fún Jóábù pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tẹ Kúṣì lẹ́yìn.”Jóábù sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìhìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”

23. Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.” Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Áhímásì sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kúṣì.

24. Dáfídì sì jókòó lẹ́nu odì láàrin ìlẹ̀kùn méjì: Álóre sì gòkè òrùlé bodè lórí odi, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.

25. Álóre náà sì kígbe, ó sì wí fún ọba.Ọba sì wí pé, “Bí ó bá ṣe òun nìkan ni, ìhìn rere ń bẹ lẹ́nu rẹ̀.” Òun sì ń súnmọ́ tòsí.

26. Álóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré: Alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.”Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìhìn rere wá.”

27. Álóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáre ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Áhímásì ọmọ Sádókù.”Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìhìn rere wá!”

28. Áhímásì sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí Olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.”

29. Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Ábúsálómù, ọmọdékùnrin náà bí?”Áhímásì sì dáhùn pé, “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.”

30. Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró nìhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́.

31. Sì wò ó, Kúṣì sì wí pé, “Ìhìnrere fún Olúwa mi ọba: nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.”

32. Ọba sì bi Kúṣì pé, “Àlàáfíà kọ́ Ábúsálómù ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?”Kúṣì sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀ta Olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 18