Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 18:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Dáfídì sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Jóábù lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Ábíṣáì ọmọ Serúíà àbúrò Jóábù lọ́wọ́ àti ìdàmẹ́ta lè Ítaì ará Gítì lọ́wọ́, Ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkárami yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.”

3. Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ìwọ kì yóò bá wa lọ: nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tílẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò násní wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbàarún wa: nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá.”

4. Ọba sì wí fún wọn pé, “Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe.”Ọba sì dúró ní apákan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọrọrún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.

5. Ọba sì pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítaì pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Ábúsálómù.

6. Àwọn ènìyàn náà sì jáde láti pàdé Ísírẹ́lì ní pápá; ní igbó Éfúráímù ni wọ́n gbé pàdé ijà náà.

7. Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ẹgbàáwá ènìyàn.

8. Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà: igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà.

9. Ábúsálómù sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ábúsálómù sì gun orí ìbaka kan, ìbaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.

10. Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi rí Ábúsálómù so rọ̀ láàrin igi óákù kan.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 18