Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 15:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yin èyí náà, Ábúsálómù sì pèṣè kẹ̀kẹ́ àti ẹsin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀.

2. Ábúsálómù sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apákan ọ̀nà ẹnu ibodé: bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá.”

3. Ábúsálómù yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ sá dára, ó sì tọ́: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.”

4. Ábúsálómù a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ ọn láti tẹ́ribá fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dì í mú, a sì fí ẹnu kò ó lẹ́nú.

6. Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀.

7. Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hébírónì.

8. Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 15