Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 14:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ábúsálómù sì ránṣẹ́ sí Jóábù, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá.

30. Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Jóábù gbé ti èmi, ó sì ní ọkà níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì tinábọ̀ ọ́.” Àwọn ìrànṣẹ́ Ábúsálómù sì tinábọ oko náà.

31. Jóábù sì dìde, ó sì tọ Ábúsálómù wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tinábọ oko mi?”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 14