Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 14:19-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Jóábù kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láàyè, Olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Jóábù ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.

20. Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Jóábù ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: Olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ańgẹ́lì Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”

21. Ọba sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”

22. Jóábù sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Jóábù sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, Olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”

23. Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù.

24. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.

25. Kó sì sí arẹ́wà kan ní gbogbo Ísírẹ́lì tí à bá yìn bí Ábúsálómù: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.

26. Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọ̀ọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba.

27. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.

28. Ábúsálómù sì gbé ni ọdún méjì ní Jérúsálẹ́mù kò sì rí ojú ọba.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 14