Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 12:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi.”

29. Dáfídì sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á.

30. Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ talẹ́ńtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀.

31. Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtùlẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì. Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 12