Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 11:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba náà ń jáde ogun, Dáfídì sì rán Jóábù, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Ísírẹ́lì; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n sì dó ti Rábà. Dáfídì sì jókòó ní Jérúsálẹ́mù.

2. Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dáfídì sì díde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò.

3. Dáfídì sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Báṣébà, ọmọbìnrin Élíámì, aya Úráyà ará Hítì.

4. Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀: nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.

5. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dáfídì, ó sì wí pé, “Èmi lóyún.”

6. Dáfídì sì ránṣẹ́ sí Jóábù, pé: “Rán Ùráyà ará Hítì sí mi.” Jóábù sì rán Ùráyà sí Dáfídì.

7. Nígbà tí Ùráyà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dáfídì sì bi í léèrè báwo ni Jóábù ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe.

8. Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹṣẹ̀ rẹ.” Ùráyà sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 11