Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 1:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’“Mo dáhùn pé, ‘Ará a Ámálékì,’

9. “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láàyè.’

10. “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún Olúwa mi.”

11. Nígbà náà ni, Dáfídì àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.

12. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti fún àwọn ọmọ ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.

13. Dáfídì sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?”O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Ámálékì.”

14. Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?”

15. Nígbà náà Dáfídì pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.

16. Nítorí Dáfídì wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’ ”

17. Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀,

18. Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jáṣárì):

19. “Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ.Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!

20. “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì,ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì,kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀,kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 1