Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 9:31-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32. Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀.

33. Jéhù sọ wí pé, “Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀!” Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

34. Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”

35. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin-ín, wọn kò rí nǹkankan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ ọ rẹ̀ méjèèjì.

36. Wọ́n padà lọ sọ fún Jéhù, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbì wí pé: Ní orí oko Jésérẹ́lì ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésébélì.

37. Òkú Jésébélì yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jésérẹ́lì, débi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jésébélì ni èyí.’ ”

Ka pipe ipin 2 Ọba 9