Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 4:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà tí gbogbo ìgò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.”Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìgò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́.

7. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbésè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”

8. Ní ọjọ́ kan Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun.

9. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń ṣábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run.

10. Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùṣùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti àtùpà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.”

11. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Èlíṣà wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

12. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì pé, “Pe ará Ṣúnémù.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

13. Èlíṣà wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsìn yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”“Ṣé alèjẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”

14. “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Èlíṣà béèrè.Géhásì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 4