Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sunkún tọ Èlíṣà wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún Olúwa. Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.”

2. Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?”“Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.”

3. Èlíṣà wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìgò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré.

4. Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ̀kùn dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìgò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kóo sí apákan.”

5. Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ilẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìgò wá fún un ó sì ń dà á.

6. Nígbà tí gbogbo ìgò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.”Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìgò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́.

7. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbésè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 4