Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 3:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun.

17. Nítorí èyí ni Olúwa wí: O kò níí rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.

18. Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa, yóò sì fi Móábù lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.

19. Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódí àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú. Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run.”

20. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ ọrẹ, níbẹ̀ ni omí ṣàn láti ọ̀kánkán Édómù! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi.

21. Nísinsìnyí gbogbo ará Móábù gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà: Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.

22. Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, òòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Móábù ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀.

23. “Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsìn yìí sí àwọn ìkógun Móábù!”

24. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Móábù dé sí ibùdó ti Ísírẹ́lì, àwọn ará Ísírẹ́lì dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ. Àwọn ará Ísírẹ́lì gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Móábù run.

25. Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run. Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára. Kíríháráṣétì nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní àyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kanakáná yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà.

26. Nígbà tí ọba Móábù rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin (700) onídà láti jà pẹ̀lú ọba Édómù, ṣùgbọ́n wọn kò yege.

Ka pipe ipin 2 Ọba 3