Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 3:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èlíṣà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jèhósáfátì ọba Júdà, Èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ.

15. Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí mú wá fún mi ohun èlò orin olókun.”Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Èlíṣà.

16. Ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun.

17. Nítorí èyí ni Olúwa wí: O kò níí rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.

18. Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa, yóò sì fi Móábù lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.

19. Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódí àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú. Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run.”

20. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ ọrẹ, níbẹ̀ ni omí ṣàn láti ọ̀kánkán Édómù! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi.

21. Nísinsìnyí gbogbo ará Móábù gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà: Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.

22. Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, òòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Móábù ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀.

23. “Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsìn yìí sí àwọn ìkógun Móábù!”

Ka pipe ipin 2 Ọba 3