Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 25:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù

9. ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná.

10. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀.

11. Nebukadinésárí olórí ẹ̀ṣọ́ Kó lọ sí ìgbékùn gbogbo ènìyàn tí ó kù ní ìlú, àti àwọn Ísánsà àti àwọn tí ó ti lo sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílón.

12. Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀sọ́ fí àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àti orí pápá.

13. Àwọn ará Bábílónì fọ́ ọwọ́n idẹ sí túútúú, àti ìjòkòó àti agbada ńlá idẹ tí ó wà nílé Olúwa wọ́n sì kọ́ idẹ wọn sí Bábílónì.

14. Wọ́n sì kóo lọ pẹ̀lú àwo ìkòkò ọkọ́, àlùmágàjí fìtílà, síbí àti gbogbo ohun èló idẹ tí wọ́n lò nílé tí wọ́n fi sisẹ́.

Ka pipe ipin 2 Ọba 25