Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 24:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà ìjọba Jéhóíákímù, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì gbógun sí ilẹ̀ náà, Jéhóíákímù sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinéṣárì.

2. Olúwa sì rán àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Aráméánì, àwọn ará Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì. Ó rán wọn láti pa Júdà run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípaṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.

3. Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Júdà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.

4. Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjìn.

5. Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóíákímù, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Júdà?

6. Jéhóíákímù sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

7. Ọba Éjíbítì kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Bábílónì ti gba gbogbo agbégbé rẹ̀ láti odò Éjíbítì lọ sí odò Éúférátè.

8. Jéhóíákínì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a sì máa jẹ́ Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátanì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin 2 Ọba 24