Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 20:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ ó dára.” Heṣekáyà dáhùn. Nítorí ó rò wí pé, “Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi?”

20. Ní ti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó kù nípa ìjọba Heṣekáyà, gbogbo ohun tí ó ṣe tan àti bí ó ti ṣe adágún omi àti ọ̀nà omi náà nípa èyí tí ó gbé wá omi sínú ìlú ńlá, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìgbéṣẹ̀ ayé àwọn ọba àwọn Júdà?

21. Heṣekáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀: Mánásè ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 20